joyce · pdf filea jọ ma nsọ̀rọ̀ pọ̀ íi gbogbo igba, ko si ohun ti mo...

48

Upload: tranhuong

Post on 01-Feb-2018

285 views

Category:

Documents


6 download

TRANSCRIPT

P.O. Box 5, Cape Town 8000

JOYCEMEYER

SỌ FÚN WỌN PÉ MO FẸ́RÀN WON

Ìrọ̀rùn òtítọ́ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run sí ọ

Unless otherwise indicated, all Scripture quotations are taken from THE AMPLIFIED BIBLE: Old Testament.

Copyright © 1962, 1964 by Zondervan Publishing House (used by permission); THE KING JAMES VERSION; and from

THE AMPLIFIED NEW TESTAMENT Copyright © 1958 by the Lockman Foundation

(used by permission).

Copyright © 2014 by Joyce Meyer Ministries – South Africa

All rights reserved. No part of this publication may be reproduced, distributed, or transmitted in any form or by any means, or stored in a database or retrieval system, without the prior written

permission of Joyce Meyer Ministries – South Africa.

Joyce Meyer Ministries – South AfricaPO Box 5, Cape Town, 8000

Phone: +27 (0) 21 701 1056Website: www.joycemeyer.org

Go to tv.joycemeyer.org to watch Joyce’s messages in a variety of languages

Tell Them I Love Them – Yoruba (Nigeria)Not For Resale

Ìtóka

ÌFÁÀRÀ1. Ọlọ́run Fẹ́ràn Rẹ! 2. Ǹjẹ́ Mo Dára Tó? 3. ÌFẹ́ Jẹ́ Ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ 4. Ìfẹ́, Ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ Àti Ìgbàgbọ́ 5. Òmìnira Kúrò Nínú Ìbẹ̀rù 6. Ìfẹ́ Amáa Kónimónra 7. Ìfẹ́ Ọlọ́run Áyí Ọ Padà

Níní Ìrírí Ìgbé Ayé Ọ̀tunÀdúrà ÌgbàlàNípa Ẹni Tí Ó Kọ Ìwé Yìí

ÌFÁÀRÀ

Mo gbàgbọ́ wípé ohun ti àwọn ènìyàn nílò jùlọ ni ìfarahàn ìfẹ́ Ọlọ́run fún ayé ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ìmọ̀ yí niyíò fún wa ní ìpìlẹ̀ fún ìbádọ́rẹ̀ẹ́, àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ àti ìgbé ayé Kristianí aṣẹ́gun.

A kò nílò ìmọ̀ orí nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ohun tí anílò ni ìfarahàn ìfẹ́ Rẹ̀ nínú oókan àyà wa. Ẹ̀mí mímọ́ nìkan lólè ṣe èyí, èyí yíò di síṣe bí abá ti ńro àròjinlẹ̀ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, tí a sì dá ìfẹ́ Ọlọ́run mọ̀ nínú ayá wa, kí á sì máa wá ìfarahàn yí nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti nípasẹ̀ àdúrà.

Fífaramọ́ wípé Ọlọ́run fẹ́ràn gbogbo aráyé Ó sì rán Jesu Kristi láti kú fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ aráyé rọrùn.

Sùgbọn, gbígbàgbó pe Ọlọrun fẹ́ràn rẹ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ti atiran Jesu lati ku fun ìwọ nìkansoso to ba jẹ ìwọ ́ nikan lowa lorilẹ alàyè, ko bati nira.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ìgbé aye kristiani to ni ìtẹ̀ba ọkan, ni ìgbẹ̀yìn moni iriri ifarahan ifẹ Ọlọrun fun aye mi. Ọlọrun ninu Ore òfẹ́ rẹ fi han mi, ni pasẹ̀ Ẹmi mimọ ifẹ rẹ funmi ni ipele ìgbésí ayé mi. Ìfihàn eyọ kansoso yi, loyi igbe aye mi ati ibadọre pẹlu rẹ pada.

Àdúrà mi ni wipe, bí o ṣe ńka ìwé yi, o ní ìfarahànn ìfẹ́

Ọlọrun fun aye rẹ. Mo gba ọ ní ìyànjú ki o kàá ni ṣị́sẹ̀ n tẹ̀lé, ki o lòó gẹ́gẹ́bí atọ́nà lati kẹ́kọ̀ọ́ síi nípa ìfẹ́ Ọlọrun ninu Bibeli, ki o si ro àròjinlè lórí àwon ẹsẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ati awọn èrò ọkàn ti yio máa jẹyo lati ewé dé ewé

Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ gan, Ó sì fẹ́ kí o mọ̀, àti kí o sì ní ìrírí ìfẹ́ Rẹ̀ lójojúmọ́, nínú gbogbo ọ̀nà ayé rẹ gẹ́gẹ́bí Ó ti ṣe fún mi. Níbáyìí, mo jọ̀wọ́ ìwé yìí fún ọ pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, ní mímọ̀ wípe nkò jẹ́ ǹkankan lẹ́yìn Ọlọ́run, àti wípé ìfihàn àti òye yìí ó wù kí nní nínú ọ̀rọ̀ Rẹ, ore ọ̀fẹ́, Ọlọ́run ni.

1

ỌLỌ́RUN FẸ́RÀN RẸ!

“NITORI Ọlọ́run fẹ́ araye to bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, ti o fi ọmọ bibi Rẹ̀ nikansoso fun wa, ki ẹnikẹ́ni to ba gbagbọ, maṣe ṣègbé, sùgbón ki o le ni iye ainipekun.”

– JOHANU 3:16

Ọlọ́run nílò ìdílé O si ńfẹ́ láti jẹ́ Bàbá fuń wa. A ṣe ẹ̀dá wa lati ni ìbánidọ́rẹ̀é pẹ̀lú Rẹ̀ àti wípé a jẹ́ ọmọkùnrin ati ọmọbìrin Rẹ̀, kí abàálè gbé ìgbé ayé ànító ati àníṣẹ́kù ti Kristi ku fun, lati fifun wa. Eyi túmọ̀ si wipe, ofẹ́ ki a fẹ̀yìnti Oun, ki a gbẹkẹle Oun, ki a fẹran Rẹ, ki asi fi aaye gba lati fẹran wa pada. O fẹ́ ki a gbẹ́kẹ̀lé oun, ati wipe ki a kepe Oun nigbati aba nilo Ohun kan: O fẹ ni Ibanidọre pẹlu enìkọ̀ọ̀kan wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ wa ni a nfi ojú gbòòrò wo Johanu3:16. Bẹ́ẹ̀ ni, momọ̀ pe Jesu ku fun gbogbo araye, sugbon eyi kii ṣe gbogbo gboo eniyan nikan bi kose pe o ku fun enìkọ̀ọ̀kan wa, ati fun ìwọ pẹ̀lú. O jẹ́ òtítọ́ pe ti o ba jẹ́ ìwọ nikan ni o wa lórílẹ̀ ayé, Jesu ko ba ku fun ìwọ nikan, ko ba fi ara da iya fun ìwọ nikan. Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ púpọ̀, ìfẹ́ Rẹ̀ ko si lopin. Jer31:3

Ní ọjọ́ kan, bi mo se nwa Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ, Ọlọ́run ba mi sọ̀rọ̀, oni, Joyce, ìwọ jẹ́ eyin oju mi, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Ọ̀ta fọhùn, oni, ǹjẹ́ eyi kii ṣe ìgbéraga bi? Taa ni onfi ara rẹ pe? Bẹ́ẹ̀ ni mo jáwọ́ ninu ero bi eyi.

Ti aba mo bi aṣe ṣe Pataki to, ati bi aṣe se iyebíye to ninu ẹ̀bùn, tálẹ́ntì ati ìlèṣe ti Ọlọ́run fi fun wa, loóòtọ́ ero wonyi le fara jọ igberaga, sugbon o jẹ́ òtítọ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa yàtọ̀, asi ṣe Pataki ni ìsẹ̀dá Ọlọ́run, eyi ti o jasi pe Ọlọ́run lodi si ifara wera, Oun lo dawa bi óṣe wùú.

Ní bímo ṣe ńronú lórí ǹkan tí Ọlọ́run bá mi sọ nínú ọkàn mi, mo ya àwòrán arábìnrin tó dúró sí ilé ìtajà níbití ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso wa níbẹ̀ jaburata o wo gbogbo rẹ̀ yíkáyíká, o si fẹ́ lati mu ẹyọ kan ti o dára lójú rẹ̀. Òye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa yémi wipe, èmi ni eso to dara jùlọ loju Rẹ̀. Emi ni eniyan ọ̀tọ̀. Eleyi ko tọ̀nà, sugbọn, woo, Ọlọ́run nwo olúkúlùkù eniyan kọ̀ọ̀kan wa bayi. Ki se wipe o sọ pe o dara ju awọn ẹlomiran lọ tabi wipe awọn ènìyàn tó kù kò sunwọ̀n. O nsọ wipe gbogbo wa ni a yàtò. Ọlọrun sọ ninu Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, si gbogbo olúkúlùkù eniyan. Iwọ ni ẹyinjú Olódùmarè.

Ní àkókò yí, nkò gba ohun ti Ọlọ́run ńbámi sọ gbọ́, nítorí kò tọ̀nà lati ro iru nkan bayi nipa emi tìkaláraàmi. Sugbọn lẹ́yìn ọjọọ́ méjì, mo si Bibeli mi si, orin Dafidi 17:8 níbẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ yi ranju mọ́ mi kankan “pamí mọ́ bi Ọmọ - Ojú, pa mi mọ lábẹ́ Òjìji Ìyẹ́ - apá rẹ” mo wa wipe, Ha! Ọlọrun ni yi, ẹyinjú Olódụ̀marè ni mo jẹ́. Ọ̀rọ yi wa mu inu mi dun, o mu mi yàtọ̀,

nigba ti mo sàsàrò lori rẹ̀. Ǹjẹ́ o tilẹ̀ mọ̀ wipe o ṣe iyebiye loju Ọlọ́run, o si fẹ́ ki o mọ wipe oyàtọ̀, o ni iye lori, o ṣe iyebiye ati wipe Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ. Gbogbo eniyan lo pòùngbẹ ki won ni ìfẹ́ oun ninu Ọkàn wọn. Ọlọ́run ṣèdá wa bẹ ni. Ọ̀pọ̀ gbàgbọ́ wipe Ọlọ́run fẹran araye, o si tun ni ìfẹ́ Jesu. Sugbọn ó ni awọn eniyan lara lati gbàgbọ́ wipe Ọlọrun fẹran wọn pèlú. Síbe ̀síbè, Ọ̀rọ̀ na kọ́ wa wipe Ọlọ́run fẹran wa gẹ́gẹ́ bi O ti fẹran Jesu. Johanu 3:16 fi eleyi fihàn wa. Ó sì fẹ́ tú ìfẹ̀ rẹ̀ ati ibukun rẹ̀ sinu aye wa gẹ́gẹ́ bi o ti fẹran Jesu ti O si bukun fún un. Johanu 5:20 wipe. “Nitori Baba fẹ́ràn Ọmọ, o si fi ohun gbogbo ti Oun fun rarè nṣe han an, Oun o si fi iṣẹ́ ti o tobi ju wọnyi lọ han an, ki ẹnu ki o le ya yin”.

Ọlọ́run sọ níhìnyìí, Èmi ńṣe àwon ohun ńlá yìí nípasẹ̀ Jesu Kristi, ohun ti o tóbi ju èyílọ, eyi ti yio ya yin lẹ́nu. Ọlọ́run ńfẹ́ lati ya wa lẹ́nu nipa síṣe ohun iyanu fun igbadun ati idunnu tiwa. A ma nka ọ̀rọ̀ Bibeli sugbọn a ma ńpàdánù ohun ti Ọlọ́run fẹ́ ṣe fun wa, pàápàá jùlọ nípasẹ̀ ara ẹni. O fẹ́ ki a wo ohun iyanu nla ti o ṣe nipasẹ, Jesu ki a si gbàgbọ́ pe O le ṣe jùbẹ́ lọ pèlú nípasẹ̀ ̀ awa na. Ninu Johanu 14:12 Jesu wipe, “Ẹni ti o bá gbà mí gbọ́ iṣẹ́ ti Èmi ńṣe ni òun náà yíò máa ṣe pẹ̀lú, iṣẹ́ ti o tobi ju wọ̀nyí lọ ni yíò si ṣe, nítorí tí Èmi ńlọ sọ́dọ̀ Baba”.

Ọlọ́run ńṣe onírúurú nkan lójojúmọ́ fun awọn eniyan nitori ti O fẹ́ràn wọn, síbẹ̀ won ko mọ̀ọ́. Fún àpẹrẹ, ronu nipa eleyi. Lójojúmọ́ bi oòrùn bá ràn, ó nràn fun èmi ati ìwọ. Ododo ntan ni orisirisi fun igbadun ọmọ eniyan. Aye ti Ọlọrun da lẹ́wà, O si fẹ́ ki agbadun rè. Gen. 1 wipe Ọlọrun fun eniyan ni ìjẹgàba

o si wi fun eniyan pe ki O ṣe amulo gbogbo oun isẹda fun iwulo Ọlọ́run ati ti eniyan. Bi Òjò ba rọ̀ ni akoko rẹ̀, o ńrọ̀ fun ọ gẹ́gẹ́bí eniyan. Ti yìníin bádé, ó dé fun ọ. Ìṣísẹ̀ rẹ, Ọlọ́run ńtọ́ ọ, O si ńwò ọ́. Deutranomi 7:9 wipe.” Nitori naa, ki ìwọ ki o mò pe Olúwa Ọlọ́run rẹ, Oun ni Ọlọ́run, olóòótọ́, ti npa májẹ̀mú mọ́ ati aanu fun awọn ti o fẹ ẹ, ti wọn si pa ofin rẹ mọ de ẹgbẹ̀rún ìran”.

Ìfẹ́ Ọlọ́run si wa jẹ́ alaini osunwọn ati titi láéláé. Ọ̀pọ̀ ninu wa lero wipe nṣe lagbé ẹrù wúwo le Ọlọ́run lọ́rùn, nípa àṣìṣe ati ìkùnà wa, ṣugbọn a ko le ṣebẹ́ẹ̀ rara. Ohun yo wu ki aṣe. A ko le dawo ìfẹ́ Rẹ̀ duro lori aye wa. Ìfẹ́ ki se ohun ti Ọlọrun ṣe, ìfẹ́ ni Ọlọrun fúnrarẹ̀.

Bí o bá lérò wípé ìwọ ni ẹni náà tí ó burú jù fún Ọlọ́run láti ni ìfẹ́ Rẹ̀, àṣìṣe lo ṣe o. Ko si kòtò ti o jin fun Ọlọ́run ju ti ko le wọ inu rẹ̀, lati fa ọ́ jade. Ọlọ́run ni ètò lati mu ọ bọ̀ sipo. Kiṣe pe yio dari ẹ̀ṣẹ̀ jìn ọ́ nìkan, sugbọn yio gbàgbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, a nu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kuro, bi ìlà orun ti jinna si ìwọ̀ orun. Orin Dafidi 103:10-12 O le wipe, mo gba Jesu sinu ọkan mi, mo si fẹ́ràn Rẹ̀. Ṣugbon mo bere lọ́wọ́ rẹ, báwo loṣe gbàgbọ́ pe Jesu fẹ́ràn rẹ to? Ìfẹ́ titi láíáíi ati ìfẹ́ àìní òṣùnwọ̀n Ọlọ́run. O jẹ́ ẹ̀kọ́ ti o rọni lọ́rùn, síbẹ̀, o jẹ́ ìpìlẹ̀ ti ó yanjú ti Ọlọ́run gbọ́dọ̀ fi lé lẹ̀ ninu ayé rẹ, ki òyé ohun to ba ku le ye ọ. Mo gbàgbọ́ wipe ohun ni ìbẹ̀rẹ̀ iwosan inu ayé ẹ̀dá.

Ohun yì ó wù ti o le kẹ́kọ̀ọ́ ni pa rẹ̀ ati bi o ba le ṣe ni ọ́ lara to lati kẹ́kọ̀ọ́ ati lépa ohun ti Ọlọ́run, ti o ko ba faramọ́,

wipe ìfẹ́ Ọlọrun si ọ jẹ́ ẹ̀bùn ọ̀fẹ́, o ki yo le ṣe àṣeyọrí to pọ̀ ni biba Ọlọ́run rìn. Nipa ìgbàgbọ́ ni a fi ńrí ǹkan gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run, ìgbàgbọ́ ńṣiṣẹ́ nipa ìfẹ́. Galatia 5:6. Àyàfi bi a ba gba ìfẹ́ Ọlọ́run, a kò lerí Ohun kóhun gbà. Ìfẹ́ Ọlọ́run ran ni lọ́wọ́ lati máa gbé láìbẹ̀rù.

1 Johanu 4:18 èyí to ṣe kókó sí gígbádùn ayé ẹni àti mímú àyànmọ́ ṣẹ. Ǹjẹ́ o ṣetán lati gba ìfẹ́ Ọlọ́run fun ayé rẹ lọ́fẹ̀ẹ́ bí? Ki ṣe fun títà, o kò lè ràá nípa iṣẹ́ rere, ohun tío nílò láti ṣe ni kí o gbà, kí o gbà, àní kí o gbà.

2

ǸJẸ́ MO DÁRA TÓ?

“Ìrètí kii si doju ti ni, Nitori a ti tan ifẹ Ọlọ́run si wa lọkan lati ọdọ ẹmi mimọ tia fi fun wa. Nitori igba ti a wa jẹ alailera, ni akoko ti oyẹ Kristi ku fun awa alaiwa-bi-Ọlọrun. Nitori o ṣowọn ki enikan ki o to ku fun olododo, ṣugbọn fun eniyan rere boya elomiran le daba ati ku. Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ Oun papa si wa han ni eyi pe, nigba ti a wa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi ku fun wa. Melo melo si ni ti a da wa lare nisisiyi nipa ẹjẹ Rẹ, ni a o gba wa la kuro ninu ibinu nipasẹ rẹ̀. ǹjẹ́ bi, nigba ti awa wa ni ọ̀tá, a mu wa ba Ọlọrun laja nipa iku Ọmọ Rẹ, melo melo, nigba ti a la wa ni ija tan, ni a o gba wa la nipa ìye Rẹ̀.”

– ROMU 5:5-10

Ó rọrùn lati gbàgbọ́ pe Ọlọrun fẹran wa, ni wọn igbati a ko ba ti se àṣìṣe. ìṣòro to wa nibẹ nipe ọ̀pọ̀ ko fẹran ara wọn, eleyi si mu ki wọn lero pe Ọlọrun ko nifẹ awọn pẹlu. Sibẹ Bibeli wipe

“kini eniyan ti ìwọ fi ńṣe ìrántí re?” (Orin Dafidi 8:4) Ịṣẹ́ ọwọ́ Olorun ni wa, ká mú lọ́nà ti ó rọrùn jùlọ, O fẹran wa nitori O ni ifẹ wa. Oun ni ifẹ (1 Johanu 4:16). Ọlọrun fẹran wa nitori O wuu bẹ!

O fẹran rẹ, ati wipe o yàtọ̀. O túmọ̀ si wipe o yàtọ̀, o si tun tayọ, eniyan ọ̀tọ̀ ni ọ́. Kòyẹ ki o dabi èmi, èmi na ko si yẹ kin dabi iwọ na. Inu rẹ kò ni dun ti o ba lo gbogbo ọjọ́ ́ aye rẹ ni fifẹran lati dabi elòmíràn àti láti fi iga gbága pẹ̀lú won. Ohun ti nkan won yi ma ńṣe ni wipe. Yio fi ààyè fun ọ̀tá lati sọ fun ọ wipe, o kò tilẹ̀ dára tó? Òtítọ́ ni wipe pẹ̀lụú Ọlọ́run o ko nilo lati dara to-Jesu ti dara tọ

O ti san ìdíyelé fun ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, O si ti jẹ gbogbo iya ti o tọ́ si ọ lati jẹ. Bibeli wipe bi O ba fẹran rẹ, ti o si ku fun ọ, to bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ti a da ọ lare nipa ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀, ǹjẹ́ O fẹran rẹ̀ bayi? (Romu 5:8-9.) O fẹran re tobẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, lati bo gbogbo àṣìṣe rẹ mọ́lẹ̀ ati wipe ki o si tun fọ̀ ọ̀ mọ́ kuro ninu àìṣedédé rẹ gbogbo.

Eléyìí ni àpẹrẹ bi moṣe lero pe Ọlọrun ma nfi oju wo awọn àṣìṣe ati àbùkù wa. Ẹjẹ́ ̀ ki a wo ọmọ kekere, bi ọmọ ọdun mẹta si mẹrin eyi ti o nṣe akiyesi bi Mama rẹ̀ ṣe nṣe iṣẹ́ Ile. O fẹran Mama rẹ̀ púpọ̀púpọ̀ debi wipe o mu ike omi kekere ati aṣọ akisa o lọ si oju ferese niwaju ita ile. O bẹ̀rẹ̀ si nu gbogbo ìdọ̀tí ti o wa nibe daradara, o si tun mu iwe ti a fi nnu ìdọ̀tí, o fi nu oju ferese na pelu. Lóòtọ́, oju ferese yi a ri bála bàla pẹlu ọṣẹ, ọmọdébìnrin yi lo aṣọ akisa iya rè ti odara jùlọ. Sùgbọ́n o wọlé wá pẹ̀lú ohun rẹ̀ fíntín, Màmá Màmá mo fọ ferese! Mo ṣe iṣẹ́, rere yi fun ọ, mo fẹran rẹ Mama.

Màmá to fẹran ọmọ yi wipe hàáà! Èyítií o ṣe yìí yà mi lẹ́nu. Oṣé to ran mi lọ́wọ́. Ni kete ti ọmọ yi ba nṣe iṣẹ́, miran lọ́wọ́ níbòmíràn, yi o tun ibẹ̀ ṣe dáradára. Níkẹyìn, yio mu

ọmọdebinrin yi lọ́kàn le, lati ran lọwọ ninu isé ile ṣiṣe, ki o ba le kọ́ bi ati ṣe isẹ́ lọ́nà tótọ́. A ni fun awon eni ti a pe gẹgẹbi ipinnu rẹ̀. (Wo Romu 8:28.) Ti o ba nṣe ohun to mọ̀ ṣe to da ọ loju to si dara, ohun ti Ọlọrun nreti lọ́wọ́ rẹ niyi. Yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ lati tẹ̀síwájú ninu ìdáwọ́lé rẹ, ti o ba ńwá ojú Rẹ̀. Yíò sì yí ọ padà si àwòrán Rẹ lati ògo de ògo (2 Korinti 3:18).

“Nítorí ẹni ti Ọlọrun ti rán ńsọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: nítorí Ọlọ́run ko fi ẹ̀mí fun un nipa òsùnwòn kékeré. Bàbá fẹ́ Ọmọ, o si ti fi ohun gbogbo le e lọ́wọ́.” (Johanu 3:34-35).

Lọ́jọ́kan nigbati mo ńkẹ́kọ̀ ninu ẹsẹ yi, mo kigbe fun ayọ̀ nigba ti mo woye pe Ọlọrun ko fun wa ni Ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nipa osunwọ̀n kekere. Ko fun wa ni kínún nihin, kinun lọ́hùn. Alaanu ni, o ṣile ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀s ju gbogbo eyi ti a nbeere tabi ti a nro lọ (Efesu 3:20)

Nínú Deutarónómì 7:6-7 “Nitori pe eniyan mímọ́ ni ìwọ fún Olúwa Ọlọ́run re: OLUWA rẹ ti yan ọ́ lati jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀ fun ara rẹ̀, ju gbogbo eniyan lọ ti n bẹ lori ilẹ̀.”

OLÚWA kò fi ìfẹ́ rẹ̀ si yin lára, bẹ́ẹ̀ ni ko yan yin, nitori ti ẹ̀yin pọ̀ níye ju àwọn eniyan kan lọ, nitori pe ẹyin ni o tilẹ kéré ju ninu gbogbo eniyan. Ohun kan wa to yẹ kómú inú ẹni dùn. Oluwa wipe: Mo gbé ìfẹ́ mi kalẹ̀ fun ọ, mo si sọ fun ọ pe o jẹ́ mímọ́. Mo sọ fun ọ pe o yàtọ̀. Mo yàn ọ́ kise wipe o dara funra rẹ, sùgbọ́n nitori mo mí ìfẹ́ rẹ. Ǹjẹ́ o mọ ohun ti Ọlọ́run fẹ́ ko ṣe loni? Ó fẹ́ ki o gba ìfẹ́ rẹ̀. Dẹ́kun lati ma sọ fun Ọlọ́run

ohun gbogbo ti ko dara ninu ayé rẹ, o ki ṣe ìyàlẹ́nu fun. O mọ ohun gbogbo nipa rẹ, ati gbogbo àṣìṣe yowu ko le ṣe, nigbati o fa ọ́ sinu ìbádọ́rẹ̀ pẹ̀lọ́ Rẹ̀.

Isoro to tobi jùlọ ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ eniyan ní ni wipe a ko fẹran ara wa. Nitori idi eyi, a ko ni igbagbọ pe Ọlọrun fẹran wa tabi pe elomiran tilẹ fẹran ẹni. A lero wipe, bawo ni won o ṣe ṣé? Mo ti di ẹni yẹ̀yẹ́! Ti o ba gbagbọ pe eniyan buruku ni ọ́, óṣeéṣe ki o máa hùwà bakanna. Òtítọ́ ibẹ̀ ni wpe, o ko le gun oke kọja aworan ti o ni nipa ayé rẹ ninu ọkàn. Isoro to pọ̀jù ti mo ni na ni wipe mi o fẹ́ràn ara mi, mo si wa nlo gbogbo akoko mi, lati yipada si nkan ti mo ro wipe, o yẹ kin njẹ́. Fun àpẹrẹ, mo lero wipe mo ti le sọ̀rọ̀ ju, nitori idi eyi mo gbiyanju lati dákẹ́jẹ́. Sugbon nigbati mo dákẹ́jẹ́ ọkàn mi pòríru osi sókùnkùn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ eniyan lo si fẹ́ mọ̀ èrèdí ti mo fi dákájé. Mo wa ro wipe, èyín le sọfún mi pe ẹnu mi gbọ̀rọ̀ mo wa ngbiyanju lati ma sọ̀rọ̀ púpọ̀. Efimí sílẹ̀.

Èmi kòlè so fún ọ iye ọdún ti mo fi la iṣoro yi kọjá ti mo si n wọnú wàhálà pèlú ọ̀rọ̀ ẹnu mi, Nitori mo n gbiyanju lati yi pada. Èṣù si ṣetán nigbogbo igba lati sọ fun mi bi aye mi se burú to, nigbogbo igba to ba ṣẹlẹ̀ nitori o n fẹ́ ki ìkùnà ati ìdálẹ́bi kún inú mi. O wá ye mi bi gbigba Ọlọrun gbọ́ pe Oun si fẹran rẹ nigbati o ba ṣìwàhù ṣe ma ńjẹ́ ípèníjà ńlá.

Ọlọ́run fẹ́ ki a di òmìnira kuro lọ́wọ́ ìdálẹ́bi ati ìjákulẹ̀, sùgbọ́n a nilo ìgbàgbọ́ ati ìgboyà lati di ominira. Ǹjẹ́ o mọ̀ wipe ko si bi idara eni lẹ́bi rẹ ṣe le jinlẹ̀ to, ko si eyiti o le san ìdíyelé

àṣìṣe rẹ. Mo tun sọ lẹ́kàn si, gbị́gbàgbọ́ pe Ọlọrun fẹran rẹ nigbati o ba ṣe àṣìse jẹ́ ìpènijà ńlá.

Nísisiyì èṣù ágbìyànjú lati da ọ loro pẹ̀lú ero wipe o burú gan. O tun ti ṣe àṣìṣe nisisiyi, a wa sọ wipe “talo ro pe ojẹ́ na? Ọlọ́run kò ní bùkún fún ọ ---- okò bá ti ṣe dáradára jù bẹ́ lọ. O kò le sọ fun eniyan nipa Jesu nisinsiyi. Ọlọrun ko le lo ọ́, ko si le gbọ adura rẹ. O kò le ṣe ohun kan to dara.

Àsìkó yi ni igbagbọ ati igboya ninu Ọlọrun gbọdọ ru soke ki o si wipe: Baba, mo ti se aṣiṣe, mo si bẹ̀bẹ̀ wipe ki o dariji mi. Mo kábàámọ̀ fun ohun ti mo ṣe, mo bẹbẹ fun idariji. O dara ki a fun satani lesi ọ̀rọ̀. Ran létí wipe Jesu ti se ètùtù fun ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati dáríjì mí, mo si ti di ominira kuro lowo ìjákulẹ̀ ati ìdálẹ́bi. Agbára to ńbe ninu ọ̀rọ̀ Ọlọ́run eyi ti o siṣẹ́ ninu aye mi, yi o ru ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ ati ìgbàgbọ́ mi soke ninu Rè. Nígbàyí lo o wa gbadun aye rẹ, wa tun di ẹni ibukun fun ẹlomiran.

O le ma ro wipe, kíni ìdí ti mofi ńṣe àṣìse búburú ní gbogbo ìgbà? Emi na ma nni iru ero yi lọ́kàn mi, a ya fi igba ti mo dẹ́kun lati ma dara mi lẹ́bi ni tori ọ̀rọ̀ yi. Nigbati o ba dẹkun ati ma gbe igbe aye ìjiákulẹ̀ ati idalẹbi lori aṣiṣe rẹ, yi o ran ọ lọwọ lati dẹkun re. Ìjákulẹ̀ at idalẹbi ma ńwọ eniyan lọrun, o si nfa iporuru ọkan debi pe o ki yio le di ominira. O ma ńsọ eniyan di aláìlágbára, o si ma ńrọrùn lati subú sínú ẹ̀ṣẹ̀. Ìdí nìyí ti o fi nilo idaniloju nipa ẹ̀bùn idariji ẹ̀ṣẹ̀ lati ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. O nilati mọ̀ bi aṣe ngbe igbe aye igbagbọ ninu ọrọ Ọlọrun, ki a mà si má gbèé ninu ijakule. Ọ̀tá yio wipe, ṣe o lero pe oko

ni ìbànújẹ́ nitori eyi? Kini idi, o nilo lati banújẹ́ fun wákàtí díẹ̀. Ohun to burú lo ṣẹ yìí. Ohun tí o nílò lati sọ ni wipe rárá, nkò ní banújẹ́ rárá.

Nídìí eyi gbàdúrà si Ọlọrun ko ran ọ́ lọ́wọ́, ko si fun ọ ni Ore-ọ̀fẹ́ lati gbọn gbogbo ero yi danu, ki o si tẹsiwaju. Ìsẹ́jú die ti o ba fi ṣe eleyi le kọ́kọ́ lera, sugbon yio rọrùn níkeyìn.

Ninu Ìsáyà 53 a ri ka wipe Jesu ru ẹ̀ṣẹ̀ wa, o si ru gbogbo ìjìyà wa (ati idalebi wa) Satani ko fẹ́ ki o di ominira kuro lọwọ idalebi. Kini idi? Nitori ti o ba di ẹni idalẹbi, o ki yio le gba ìfẹ́ Ọlọrun. Idalẹbi n ya eniyan kuro lọdọ Ọlọrun o ko si le gbadun ifarahan Rẹ̀, o tilẹ̀ ma nmu ki a gbẹ́kẹ̀lé ara wa dipo Olorun. O le gbé igbe aye ominira kuro lọwọ idalẹbi nipa gbigbagbo pe nigba ti Oluwa sọ wipe ore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ to lati bo` gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́lẹ̀ òtítọ́ ni O ńsọ. O fẹ́ràn rẹ, ore ọ̀fẹ́ ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn ti a fi fun ọ. Gbàá lo ni.

3

ÌFẸ́ JẸ́ ÌBÁNIDỌ́RẸ̀Ẹ́

“Àwa ti mọ̀, a si gba ìfẹ́ ti Ọlọ́run ní síwa gbọ́. Ìfẹ́ ni Ọlọ́run, eriti o ba si ngbe nimu ìfẹ́ o ńgbé ninu Ọlọrun ati Ọlọrun ninu rẹ̀.”

– 1 JOHANU 4:16

Bi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun se wipe ìfẹ́ ni Ọlọrun, O fẹ́ ki a mọ̀ bẹ́ẹ̀, ki a ni iriri rẹ̀ ati lati ṣe àkíyèsí ìfẹ́ Rẹ̀. Nibayi bawo ni o ṣe le sàkiyesi ìfẹ́ Ọlọrun? Bo ti lẹ wu ki O fẹran rẹ̀ to, ti o ko ba mọ nipa ìfẹ́ Rẹ̀, kole ṣe anfani fun ọ rara. Ronu bi inu re se ma ndun nigbati eniyan kan ba fi ìfẹẹ han si o, Ti o ba mo wipe eniyan kan ni ifẹ rẹ, o ma fun ọ ni igboya, Ọlọrun feran rẹ, o si fẹ́ fi ife na han si ọ. Ó ńpe ẹnìkọ̀kan wa sinu ijinle sísún-mọ́ni pẹ́kípẹ́kí àti ìbánidọ́rẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀. Ó fẹ́ ki a ma pe Oun si gbogbo ìdáwọ́lé wa. Ó fẹ́ ki o ma ba ohun sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́ bi ènìyàn ti n ba ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ dọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀.

Ǹjẹ́ o ni ìbásepọ̀ to dánmọ́rán pẹ̀lú Ọlọrun? Nigbati eniyan ba ṣẹ̀ṣẹ̀ di àtúnbí, a ko le ni ibaṣepo kíkún pẹlu Ọlọrun

ni kíákíá. A nilo lati dàgbà soke ninu bíbá Olorun rìn, ní ọ̀nà kannáà ti a fi nba awon eniyan dọ́rẹ̀ wọlé-wọ̀de.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà sẹ́yìn, mo jẹ́ onígbàgbọ́ ki n to mu ìrìn àjò mi pelu Ọlọrun ni ọ̀kúnkúndùn. Mo n lọ sile ìjọsìn ní ọjọ ìsinmi, mo si fi ara mi jin fun awon iṣẹ́ ile Ọlọrun, sugbọn Ọlọrun ko si ninu gbàgede aye mi. Àìlè mú àyànmọ́ ṣẹ, ati ọkàn to ṣófo jẹ́ iriri mi ni gbana. Sugbon lọ́wọ́lọ́wọ́, Oun ni mo n ro nipa Rẹ̀ ni kùtùkùtù òwúrò ati àsálẹ́ ọjọ́ aye mi gbogbo. A jọ ma nsọ̀rọ̀ pọ̀ íi gbogbo igba, ko si ohun ti mo fẹ́ràn ju ki n ma sin Ọlọrun mi, ati ki nsi tẹ lọ́rùn ni gbogbo igba. Àlàfo kan wa ninu aye ẹ̀dá ọmọ ènìyàn to si jẹ́ wipe Ọlọrun nikan lo le kún àfonífojì yi. Ko si ìlépa tabi ìpinnu to le di alafo yi. Mo gba ọ́ ni ìyànjú pe ko bèrè lọ́wọ́ ara rẹ. Bawo ni mo ṣe mu ìbádọ́rẹ̀ mi pẹlu Ọlọrun ni ọ̀kúnkúndùn? Ǹjẹ́ mo ṣe tan lati fi ìfẹ́ Rẹ̀ síwájú ohun gbogbo ninu ayé mi? Ǹjẹ́ mo le sọ̀rọ̀ bi Paulu ti ṣe ninu Ìṣe Àwon Àpósítélì 17:28. Nítorí ninu rẹ̀ ni àwa gbé wà ti àwa rin kiri, ti awa si ni ẹ̀mí wa.”

Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ, o je ́ eniyan ọ̀tọ̀ si Ọlọrun. Ó da ọ lati ni ibasepọ pẹlu Oun, Ifẹ ati ìpinnu Rẹ̀ nìyí fun aye rẹ. O nsọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ ninu ọkàn rẹ lójojúmọ́, Ẹkáàárọ̀, mo feran re. Ti oko ba i ti ma gbọ́ irúfẹ́ ọ̀rọ̀ báwọ̀nyí, ǹjẹ́ wàá bẹ̀rẹ̀ síní tẹ́tíléko, kí o sì bií

Òrẹ́ tímọ́tímọ́ mi sàkàwé Bàbà ńlá, èyíinì, Ọlọ́run tó nlọ lati ojúlé-dé-ojúlé kọ̀ọ̀kan ni ilu America ni òwúrò tójúmọ́

ba ti mọ́. Ó nlọ lati lọ sọ àsọyépọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn. Ó pèsè àga lati joko si tábìlì pẹ̀lú wọọn, ṣùgbọ́n àwon eniyan wọ̀nyí dìde, wọ́n ńwá wọn ńlọ. Lẹ́yìn èyi, wọ́n bá Ọlọrun sọ̀rọ̀ pé. Olúwa, dúró síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn ti abá parí oun ti anse lọ́wọ́ lọ́wọ́, a ó wà bá ọ sọ̀rọ̀. ẹjẹ́ ki ọ̀rọ̀ àjọsọ wa di ọjọ́mìíràn, Ọlọ́run, ó tún di ọjọ́ miran ọjọ́ ire.

Ní òpin ọjọ́ náà wọ́n padà wá. Ọlọ́run kúrò ninu ile wọn pẹ̀lú ìbànújẹ́ nitori ko si ẹni ti o wa ba Ọlọrun sọrọ ni ọjọ na. Olúkúkùkù lo nṣe ohun miran to ṣe pataki si wọn, wọn ko si ri aaye fun Ọlọrun. Máṣe aláìní àkókò fun Ọlọrun. Ti oko ba ni ri aaye lati gbadura ati lati wà níwájú Rẹ̀, ó túmọ̀ si wipe oníṣẹ́ ni ọ́. Wá àkókò lati sọ fún Ọlọrun bi o ṣe nífẹ̀ Rẹ̀ tó. Ti ohun gbogbo ba rekọja lọ, Ọlọrun nikan ni yio ku ọ́ kù. Bẹ́ẹ̀ ni. Bi o ko ba ni àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀, àfàìmọ̀ ki o ma tipẹ́jù fun ọ láti bẹ̀rẹ̀ ibanidọre pẹ̀lú Ọlọ́run.

Bàbá mi kú láìpẹ́ yi, inú mi dùn lati sọ wipe, o gba Jesu gẹgẹbi Oluwa ati Olùgbàlà rẹ̀ ni ọdún mẹ́ta sẹ́yìn ki ọlọ́jọ́ tó dé. Lótìtọ́, Baba mi lọ si ọ̀run rere, ṣugbọ́n o pàdánù ìgbé-ayé aṣẹ́gun ninu Oluwa. Igbe aye ara tirẹ nikan lo gbe. Mádèé òpin ìrìn àjò aye rẹ pẹ̀lú àbámọ̀ nitori ti o ti fi gbogbo ọjọ́ ayé rẹ ṣòfò lóró ohun ti ko tọ̀nà. Wákàtí ati akoko jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọrun, a nilati kíyèsára, bi a se nlo akoko wa. Nje o mọ̀ wipe, akoko ti eniyan ba ti lo, o ko le gba pada mọ́. Akoko ti a ba lo pẹlu Ọlọrun o ní èrè ti o pọ̀, sugbọn pupọ ninu awọn ohun miran ti ẹda nle laye, igbadun diẹ ni, a si nṣan ìdíyelé to pọ̀ fun.

Mo gbà ọ́ níyànjú lati ṣe ìpinnu lati lo ọdun tó ńbọ̀ nínú ifẹ Ọlọrun, kíkẹ́kọ̀ Ọlọrun nipa ifẹ, ki a ba le mọ̀ bi a ṣe lè gba ifẹ Rẹ̀, ifẹ Ọlọrun ńsọ ni di mímọ́, o nfun ni ni alafia, ayọ̀ ati kíkó ipa ti o dara ninu aye. Ati wipe O fe ki a farabalẹ̀ ki a si gbadun gẹgẹbi ọmọ rẹ̀. Kọ́ ẹ̀kọ́ ninu Bibeli nipa eniti Ọlọrun ise, ki o si tun mọ̀ síwájú si.

1 Johanu 4:16 wipe: “Àwá ti mọ̀, a sì ti gba ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa gbọ́, ìfẹ́ ni Ọlọ́run, ẹnití ó bá sì ńgbé nínú ìfẹ́, ó ńgbé inú Ọlọ́run àti Ọlọ́run nínú rẹ̀” ara eniyan le saláì yá si ife ni òwírọ̀. látàrí àìlágbára, tabi àìmọ̀ bóyá ìrúnú ti o báni jí lè báni kalẹ́. Ìròyìn ayọ̀ náà rèé, o le yi iwa rẹ pada nipa sisọ ọ̀rọ̀ ìmúni lọ́kànle ati ti igbagbo. Kígbe sókè, Ọlọrun fẹran mi púpọ̀. Ẹyin ojú Olódùmarè ni mo jẹ́, O si ni ètò rere fun mi. Bi o ba ńsọ̀rọ̀ nípa Ọlọrun ati ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ dípò ìsòro ati ìrírí to ńlà kọjá, ó lè yí ọjọ́ aye rẹ pada si rere.

O nílò láti bá ara rẹ sọ̀rọ̀ ki o si kiyesi pe ifẹ Ọlọrun yí ọ ka. Bibeli wipe: Ọlọrun ti ya àwòrán rẹ si àtẹ́lẹwọ́ ara rẹ̀ (Wo Isaya 49:16). Mo riì loke lọ́hùn ti o nwipe, sáà wòó, ǹjẹ́ wọn ko rẹwa bí? Mo ní ìfẹ́ wọn ganan. Wo àwọn ọmọ mi, ninu àtẹ́lẹwọ́ mi“Ó fi ọ́ síbẹ̀ lati ma ran létí lemọ́lemọ́ wipè. Òun ní ìfẹ́ rẹ, Oun si n fẹ àjọsepọ̀ to dánmọ́rán pẹ̀lú rẹ.

Máa rántí lati dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ati lati mú ìbásepọ̀ rẹ pẹ̀lú Rẹ̀ dé ojú òṣùnwọ̀n. Ní ìgbàmíràn, o le fẹ́ da iṣẹ́ rẹ duro fun igba kan lati dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o mọ ati lati sọ fun un bi o ṣe jẹ́ ìyanu to. Farabalẹ̀ ki o si fẹran Ọlọrun. 1

Johanu 4:16-17 wipe: “Ìfẹ́ ni Ọlọ́run, eni ti o si ngbé nínú ìfẹ́ yíò ma tẹ̀síwájú lati ma fẹ́ràn ati lati ma dàgbà nínú Ọlọ́run, Ọlọ́run a si ma gbe inu rẹ̀ pẹ̀lú lati mu tẹ̀síwájú. Nínú (ibasepo ati idapo mimo pelu Rẹ̀) a mu ìfẹ́ wa si pípé ati àṣepé pẹ̀lú wa. Kí á baà lè ní ìgboyà ní ọjọ́ ìdájọ́.”

Mímọ̀ daju pe Ọlọrun fẹran re yio fun o ní igboya ati ìgbẹ́kẹ̀lé ninu òdodo Rẹ̀. Gbogbo ibukun to ti pinnu fun ọ yio tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ nigbati o ba gbàá láàyè lati fẹ́ràn rẹ. Ìgbàgbọ́ gíga, ìṣẹ́gun lori ẹ̀ṣẹ̀, àlááfíà ninu okan, iwosan, aye ti o kun fun ẹbun Ọlọrun, ati ayọ yio wa jẹ tire. Awon wonyi yio te o lọwọ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ nigbati o bá gba Ọlọ́run láàyè lati fẹ́ràn re. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ma ńyí eléyì po, ti a si ma nro wipe, o dára mo ni lati fẹ́ Ọlọ́run. Lákọ̀kọ́, mo gbàgbọ́ pe o nilati jẹ́ ki Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ. nkò gbagbo pe o le fi ìfẹ́ tìrẹ han fun Ọlọ́run àyàfi bi o bákọ́kọ́ gba ìfẹ́ tirẹ̀ láàyè. Bibeli wipe a feràn Rẹ̀ nitori Oun ni o kọ́kọ́ fẹ́ràn wa. 1 Johanu 4:19.

Bí a bá mọ̀ wipe Ọlọ́run fẹ́ràn wa ti a si gba ifẹ Rè ni a o le fẹ́ràn Òun tìkalárarẹ̀ padà. A o wà ni àjọṣepọ̀ to dánmọ́rán pẹ̀lú Rẹ̀. Ó lè yà ọ́ lẹ́nu, bawo ni a se le ni ibaṣepo pẹlu Ọlọrun? Nigba ti Ọlọrun sọ fun mi lati ba Òun ṣepọ̀, mo joko sori aga, mo si wipe Ọlọrun kínni gan nísisiyì? Ó dára nkò mọ bi mo ṣe le ni ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, nítorí ni ìpele yìí, nko mọ bí ó se ni ìfẹ́ mi tó, nkò sì ní òye wipe o fẹ́ kin jẹ́ ọ̀rẹ́ ati alábàárìn fún Òun. Bi mo ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ akoko pẹlu rẹ̀, ní gbígba àdúrà àti kíka ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ati ni ọ̀pọ̀ igba ninu ìdákẹ́jẹ́ níwájú Rẹ̀, mo kọ́ bi a ṣe ńgbádùn àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.

Mo fẹ́ gbà ọ́ níyànjú láti jáde ki o si gbe ìgbésè fún Oluwai, yi o si kọ́ ọ ni ọ̀nà ti ìwọ yi o gbà lati ba ni àjọṣepọ̀. Nko ní ṣe àgbékalẹ̀ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run fún ọ. Nko fẹ́ ki o ni koko pataki ikinni, ikeji, iketa, ati bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Mofẹ́ ki Ẹ̀mí Mímọ́ darí rẹ, Ọlọ́run fẹ́ ki ara tu ọ́ pẹ̀lú Òun, ju gbogbo rẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bi Éfésù 3:17 ti sọ, ọkàn rẹ ni ibùgbé Kristi.

ÌFẸ́, ÌGBẸ́KẸ̀LẸ́ ÀTI ÌGBÀGBỌ́

“Nítorí nínú Kristi ìkọlà kòjẹ́ ohun kan, tàbí àìkolà, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ ti ńṣiṣẹ́ nípa ìfẹ́.”

– GALATIA 5:6

Púpọ̀ nínú wa ní ọ̀pọ̀ ìgbà ma ńgbìyànjú lati ni igbagbọ, o dáwa lójú pe láìsí ìgbàgbọ́ ko ṣeéṣe lati wu Ọlọrun (wo Heberu 11:6) nitori ìdí èyí, a ńsisé a si ńlàkàkà lati ni ìgbàgbọ́ síi. Sùgbọ́n ìgbàgbọ́ ma ńdàgbà nínú ọkàn wa, a si ma nri gbà nípasẹ̀ ibanidọrẹ pẹlu Ọlọrun ati gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. ọ̀nà kan soso ti ónńgbà wa ni ifihan nipase Ọlọrun. No le kọ́ ọ ní igbagbọ, ṣugbọn molè kọ́ ọ ni gbèdéke igbagbọ eyi ti yi o ma pa ọ́ lébi, o si ma ṣe ohun gbogbo lati ríi gbà. Igbagbọ ni ọwọ́ ti a nà jáde ti a si nfi gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run.

A níláti dẹ́kun ati ma tiraka lati ni igbagbọ ki a to le tẹ́ Ọlọrun lọ́rùn, ki a si ma lo gbogbo àkókò yi ati ìgbìyànjú wa pèlú Ọlọrun, ni fífẹ́ Ọlọrun ati gbígba ìfẹ́ Rẹ̀.

2 Korinti 5:7 wipe: “Àwa ńrìn nipa igbagbo [a ṣe ètò

4

aye wa ati ara wa pẹ̀lú ohun to dáwalójú, eyi ti a gbàgbọ́ ni bíbu ọlá fun ìbádọ́rẹ̀ẹ́ eniyan si Ọlọrun ati awon ohun ti àtòkè wa, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé ati ìtara mímọ́; nidi eyi a n rin] ki ṣe nipa riri.” Nigba ti mo kọkọ ka ọ̀rọ̀ ìwé mímọ́ yii, mo lero wipe Ọlọ́run ńsọ ohun ìjìnlẹ̀ to ni agbára sinu ọkàn mi. O se afihan rẹ̀ fun mi pe ki ise igbiyanju ati ilakaka mi lati ba Ọlọrun rin ni óńsisẹ́, ọ̀rọ̀ yii ńsọ wípé mo le rìn nínú ìgbàgbọ́ nìkan, lóríi gbèdéke nkan ti mo gbàgbọ́ nipa ìbádọ́rẹ̀ẹ́ mi pẹ̀lú Ọlọrun. Dúró ki o ronú nipa eyi. Bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ pe bawo ni ìbásepọ̀ mi pẹ̀lú Ọlọrun rí? Ẹnikẹ́ni to ba gbagbọ pe aláìsòdodo ni òun loju Ọlọrun, kole rin ninu ìgbàgbọ́. Ati sọ wá di ọ̀tun pẹlu Ọlọrun nípasẹ̀ ètùtù ti Jesu Kristi ṣe fun wa (wo 2 Korinti 5:21). Òdodo wa kòsí lori oun ti a gbé ṣe tabi ti a fẹ́ se, o duro lori ohun ti Jesu ti ṣe. Ẹnití o bá gbàgbọ́ wipe oun jẹ alábòsí ati ẹni ìjákulẹ̀ ati wipe Ọlọrun kò fẹ́ràn òun kò lè rìn nínú ìgbàgbọ́

Galatia 5:6 ìgbàgbọ́ ńsiṣẹ́ nipa ìfẹ́. Púpọ̀ ninu àwọn eniyan lero wipe ìwé mímọ́ sọ pe ti a ba le gbìyànjú lati fẹran ọmọnìkejì wa, nígbàyí gan ni igbagbọ tiwon yio ṣiṣẹ́ fun won, wọn a si ri ohun ti wọn fẹ́ lati gbà. Lóòótọ́, Ọlọrun fẹ́ ki a rin ninu ìfẹ́. Ko le ṣeése lati ṣe eyi àyàfi igba ti a ba kọ́kọ́ gba Olorun láàyè lati fẹran wa. O rọrun gan ni, a kole fi ohun ti a ko ni tọre fun ẹlomiran. Mo gbiyanju lọpọlọpọ ọdún lati rìn ninu ifẹ pẹlu awọn eniyan nitori mo mọ wipe àṣẹ Ọlọrun ni, ṣùgbọ́n mo ma ńkùnà àyàfi ìgbà ti mo gba ifẹ ti ko ni òsùnwọ̀n fun ayé mi.

Mo wá ní àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ówá rọ̀mí lọ́rùn lati nọwọ́ ìfẹ́

tòótọ́ si awon elọmiran. Ti oba mọ̀ bi Ọlọrun ṣe fẹ́ ọ tó, ìṣòro rẹ ko ni pọ pupọ, lati ri nkan gba lọ́wọ́ Ọlọrun ati lati ba àìní rẹ pàdé ko ni le. Idi ti awon eniyan ko fi ri gba, ni wipe won ko gbagbọ pátápátá, wipe Ọlọrun feran won lati ba aini wọn pade ki o si bukun fun won.

O lè wipe “mo fẹ́ gbàgbọ̀ bẹ́ẹ̀ sugbon bawo?” ìfẹ́ Ọlọrun wà ninu rẹ, ohun to nilo ni wipe, ki o bẹ̀rẹ̀ si ni da mọ̀ nigba ti o ba farahàn ọ́. Bibeli wipe, “A fẹ́ràn Rẹ̀, nítorí Oun ni o kọ́kọ́ fẹ́ wa (1 Johanu 4:19). Kòlè seése fun ọ lati fẹ́ Ọlọrun ti o ko ba ni ìdáni loju wipe o kọ́kọ́ fẹ́ràn rẹ.

Ìfẹ́ Ọlọrun wà ninu ọkàn rẹ... jinlẹ̀ de ìsàlẹ̀ ikùn. Ìwọ yio si da mọ̀ nígbàtí o ba ri ara rẹ gẹgẹ bi Ọlọrun ṣe ri ọ. Ọlọrun pè ọ́ ní ìyanu, arẹwà, ẹni ti ojú rẹ̀ fanimọ́ra, ẹnití ori ẹbun tí o tayọ gbà, ati pe ìwọ se iyebíye loju Ọlọrun. Ọlọrun fẹran rẹ. Ko si eniyan kan ni gbogbo àgbáálá ayé ti o le fẹran rẹ bi Ọlọrun ti ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ to. Bi o se ńse ààrò ninu ìfẹ́ Ọlọrun yi, bẹ́ẹ̀ni o gbọ́dọ̀ tú igbagbọ rẹ sílẹ̀ lati gbe igbe aye ti Ọlọrun ni fun ọ.

O kò nilo ẹlòmíràn àyàfi Ọlọrun, yio wá ran awọn eniyan tío nilo sinu aye rẹ. Òtítọ́ ni wipe bi ko ba si ẹlòmíràn lẹ́yìn ìwọ ati Ọlọrun, o dárabẹ́ẹ̀. Olọrun a wá jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ ti ódárajù. Yio wa di akẹ́gbẹ́ rẹ, ti o ko ba lẹnìkan. Ó lè di ́ Baba tabi Ìyá ti oṣe aláàní rẹ̀, ohun gbogbo tío nilo. Má ṣe àṣìse pe ki o máa bèrè ohun ti Ọlọrun lèṣe fun ọ nìkan, bèrè fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ sínú ayé rẹ. Sọ fun pe ki Ó kun ọ ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ni ìbárìn rẹ pẹ̀lú Rẹ̀. (wo Efesu 3:16-19)

Ìgbàgbí Àti Iṣẹ́ Ti Ara

Éfésu 2:8 wipe, Nípa ore òfé (Àánú Ọlọrun ti ko tọ́ si eniyan ni a fi gbà ọ́ là). Ǹjẹ́ o mọ̀ wipe o ko se ohun kankan lati di ẹni ìgbàlà? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ninu wa ni ẹlẹ́ṣẹ̀ to burújáì nigba ti Jesu gbàwá là, ẹ̀bùn igbala Rẹ̀ kii se lọ́ríi ìdiwọ̀n iṣẹ́ rere wa tabi agbára wa lati ṣe ohun tíó dára. Nitori ohun kanṣoṣo ni, Ọlọrun fẹ́ wa to bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ti ósì fi ọmọ bíbí Rẹ̀ kanṣoṣo wipe ẹnikẹ́ni ti o ba gbàgbọ́ ki o ma ṣe sègbé, sugbọn ki ole ni ìyè àìnípẹ̀kun (wo Johanu 3:16).

A lè ṣẹ àkàjúwe Ore-Ọ̀fẹ́ gẹ́gẹ́ bi ìpinnu Ọlọ́run lati lo agbára Rẹ̀ to wà ninu aye wa lati ba gbogbo aini wa pade. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run, nípa Ore-Ọ̀fẹ́ Rẹ̀ ṣe fun wa ni ìgbàgbọ́ lati di ẹni ìgbàlà, bákannáà, nítorí ìfẹ́ Rẹ̀, O tun fun wa, ni ìgbàgbọ́, lati gbàgbọ́ fun awọn ohun míràn ti a tun nilo. O le wu ọ́ pe ki àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ gba Kristi, sugbọn otitọ to wà níbẹ̀ ni pe o ko le fi ipá mú ẹnikẹ́ni lati fẹran Ọlọrun. Àdúrà nìkan lo le gbà fún wọn pé ki Ọlọrun fọwọ́ tọ́ ọkàn wọn, o ko le gba wọn là nipa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

Iṣẹ́ ti ara, tàbí èyí ti a ńgbìyànjú lati fi agbára wa ṣe, nígbà gbogbo máa ńjáwa kulẹ̀, nitori ti a gbìyànjú lati ṣe ǹkan to jẹ́ wípé Ọlọrun nikan lo le ṣe. À ńṣe iṣẹ́, a ko si ri èsì rere. Ǹkan ti a nilo nipe ki a rẹ ara wa sílẹ̀ niwaju Ọlọrun, ki a si bèèrè fún ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀. Bibeli sọ ninu 1 Peteru 5:5 Ọlọrun fúnra Rẹ̀ kọjú ìjà sí agbéraga ṣùgbọ́n o fi Ore-Ọ̀fẹ́ (ojúrere, ìbùkún) fun àwọn onírẹ̀lẹ̀.

Ore ọ̀fẹ́ Ọlọrun ṣe pàtàkì nínú ayé wa. A gbàwá là nípa Ore-Ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́. ọ̀nà kannáà ti a gbà di ẹni ìgbàlà ni ọna bo ṣe yẹ ki a máa gbé igbe ayé ẹni ---- nípa ore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ní pasẹ̀ ìgbàgbọ́! Níwọ̀n ìgbà tí a bá mọ ìpìlẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run yi nínú ayé wa, nígbà yi ni àwa yíò wá bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbẹkẹ̀le. O le rìn nínú ìgbàgbọ́ tí kìí ṣe nípā rírí. Ìwọ yio si mọ̀ ninu ọkàn rẹ wipe Ọlọrun jẹ́ olóòótọ́ yio si mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ.

Gẹ́gẹ́bí Bibeli aláfiwé ṣe wí, ìgbàgbọ́ jẹ́ gbígbé gbogbo ayé rẹ le Ọlọrun lọ́wọ́, ninu ìgbẹkẹ̀lé àti ìgboyà nínú agbára, ìmọ̀, ìṣerere Rẹ̀. (Kolose 1:4.) Bi o ṣe ńfi ààyè gba Ọlọ́run lati ni ìfẹ́ rẹ, ìwọ yíò le ṣe eléyi. Bí àsepọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run ba ṣe ńjinlẹ̀ si, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìgbàgbọ́ rẹ yíò máa dàgbà, ìwọ yíò si máa ri iṣẹ́ agbára Ọlọ́run nínú ayé rẹ ati lati ọ̀dọ̀ rẹ sí ẹlòmíràn ṣùgbọ́n o bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìfihàn ìfẹ́ Rẹ̀. Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ! Má siyèméjì.

5

ÒMÌNIRA KÚRÒ NÍNÚ ÌBẸ̀RÙ

“Ìbẹ̀rù kò sí nínú ìfẹ́ (ẹ̀rù kò sí rárá), ṣugbọ̀n ó bú jáde (ójẹ́ pípé, ó sì kún). Ìfẹ́ lé ẹ̀rù jáde ósì ti lẹ̀kùn mọ́ gbogbo ìfarahàn ìjayà! Nitori ìbẹ̀rù mu èrò ijiya dání àti pé ẹni tí o ńbẹ̀rù ko ti de ìpele ìdàgbà sókè ninu ìfẹ́ (ko si ti dàgbà sínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìfẹ́ ti o pé).”

– 1 JOHANU 4:18

A lè dé ìpele kan tójẹ́ pé ìrìn wa lójú ọ̀nà ìgbìgbọ́ dára; ní gbígbẹ́kẹ̀ lé Ọlọrun ati ninu igboya pe Ọlọrun fẹran wa. Lojiji, ki òtá wa gbógun tìwá, tabi dojú ìjà kọ wá.

Àwọn ǹkan tí ó yí ayé wa ká ---- àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú to ṣẹlẹ̀ sí wa ---- lè dan ìgbàgbọ́ wa wò. Elòmíràn kòní ìsòro púpọ̀ nípa gbígbàgbọ́ pé Ọlọ́run fẹ́ràn wọn títí di àkókò tí ǹkan bá ṣẹlẹ̀ lòdì si wọn bi eni wipe Ọlọrun kò ní ìfẹ́ wọn mọ́.

Ìgbà yí gan ni òtá ma n wa pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìdálẹ́bi láti yà ọ́ sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun gbogbo to yẹ ko ran ọ́ lọ́wọ́ ---- ìfẹ́ Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ni, kínwá leléyìí? Yíò ní “Mo ro wipẹ Ọlọrun fẹran rẹ niì. Kíló dé ti ǹkan búburú ńṣẹlẹ̀ si ọ? Óní láti jẹ́ wipe o ti ṣe

ohun búburú kan nìyẹn o, inú Ọlọrun kò dùn si ọ rárá o.

Ó rọrùn ní àkókò ìdánwò àti ìdààmú, àkókò ti ko wọ̀. tí ǹkan ko si rọgbọ , lati pàdánù ìgboyà wa nínú Ọlọ́run. Ọlọ́run kìí ṣe nkan tirẹ̀ ni igba ati akoko ti a retí pé kóṣeé. Ó ní ètò to ga ju tiwa lọ. O fẹ yi àwa tìkara wa pada ju ohun ti a ńlà kọjá lọ. O si ma lo ìṣòro wa lati ru ìgbàgbọ́ wa sókè nínú Rẹ̀ ati lati kọ́ wa ní bi a ṣe nílò lati gbẹ́kẹ̀lé Oun nìkanṣoṣo. Láàrin àwọn ìdojúkọ yìí, òye ohun ti o n ṣẹlẹ̀ sí wa le má yé wa rárá, èyí sìlè mú wa ṣubú sínú ìdẹkùn pe Ọlọrun ko fẹran wa mọ́. Ìgbà yi gan ni aní lati ráníi Romu 8:35-39 ti o wi pe kòsí ohun ti o lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọrun ati wipe a di aṣẹ́gun ninu Kristi Jesu. Ohun ti ódára jùlọ èyí ti a lèṣe, nigbati a ba wa ninu isoro tabi ìpọ́njú nipé ká kígbe sókè báyìí “ Oláwa mo mọ̀ dájú wípé o fẹran mi, mo si mọ̀ wipe ohun gbogbo yíò ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún mi”.

Nígbà míràn Ọlọ́run máa ń dáwọ́ dúró lati gbà wá, títí aó fi lérò pé o ti pẹ́jù. Ǹjẹ́ o rántí Lásárù? Ó ṣàìsàn ṣugbọn Jesu dúró pẹ́ títí tó fi di òkú, ki o to yọ́jú si awọn ẹbí rẹ̀ lati ràn wọ́n lọ́wọ́. Màrtà sọ fún Jesu pé ọ́ti pẹ́jù, sugbọn Ó mo ohun ti O ńṣe, a si mú Lasaru padà di alàyè ọkàn ní ọ̀nà tí ó lágbára ti o si fi ògo fun Ọlọrun. Ọlọrun lè má ṣiṣẹ́ ní àkókò ati igba ti awa ńfẹ́ gẹ́gẹ́bíi eniyan, sugbọn kòlè dúró pẹ́. Tí ó bá nísòro nínú aye rẹ, máa wo Ọlọrun, ki o si mú igbagbọ́ rẹ wá sí ojúṣe. Má sì jẹ́ kí ìbẹ̀rù ati ìdààmú jí ìfẹ́ Ọlọrun kúrò lọ́kàn rẹ.

1 Johanu 4:18 jẹ́ ẹsẹ ọ̀rọ̀ Ọlọrun tó ní agbára “ìfẹ́ pípé lé ìbẹ̀rù jáde” mo ronújinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yí, lati ṣe àsàrò, ni ọjọ́ kan,

òye rẹ̀ yẹẹ́ mi pé ìfẹ́ pípé lé ìbẹ̀rù jáde, Ọlọ́run sìni ìfẹ́ tí ó pé. Bí o ba ti mọ rírì ifẹ Ọlọrun si ọ, o ko ni gba ibẹru láàyè lati jọba ninu aye rẹ. Lóòótọ́ o lè ní ìbẹ̀rù, ṣùgbọ́n èyí lè mú kí o máa tẹ̀síwájú ninu Ọlọrun nitori ìwọ yíò ní ìdánilójú pé Òun ńbẹ pẹ̀lú rẹ.

Kò lè ṣeéṣe kí eniyan bẹ̀rù ìjákulẹ̀ tí ó bá mọ̀ wipe Ọlọrun fẹran re. O ni òmìnira lati gbìyànjú àwọn ohun kan nitori o mọ̀ wipe ìfẹ́ Ọlọ́run ati ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ sí ọ kìíṣe lórí iṣẹ́ ti o ṣe fún un. O kò lè jábo ́ niwọn igba ti igbẹkẹle rẹ n bẹ ninu Ọlọrun. Ona kan ṣoṣo ti o le gba kuna ni bi o ba gbẹkẹlẹ ara rẹ. Ohun gbogbo le ma ri bi o ti se ńfẹ́, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ a yípadà sí rere nigba ti o ba gbójú rẹ soke si Ọlọrun. Bi o ba wipe Ọlọrun fẹran rẹ, o kò ní bẹru ijakulẹ, ìkọ̀sílẹ̀, àìní, ọjọ́ àná, ọjọ́ iwájú, tabi ohun miran.

Ìfẹ́ Ọlọ́run tóbi o si borí ohun gbogbo. Ǹjẹ́ o lérò pé Ọlọrun to gba ọ́ la, to sọ ọ́ di ominira a tun jẹ́ kío ni ìjákulẹ̀ bí? Ṣé ó lè fi ọ́ sílẹ̀ gẹgẹbi aláìní olùrànlọ́wọ́? Sàtánì ni ọ̀tá ẹ̀mí wa, olè ati òpùró ni, sùgbọ́n Jesu fe ki a ni ìyè ayérayé kí á sì gbádùn rẹ̀. Johanu 10:10

1 Johanu 4:18 wipe kò sí ìbẹ̀rù ninu ifẹ ìfòyà kò sí rárá ṣùgbọ́n ifẹ ti ó ga èyí ti ópé, eyi tíó kún ó ńlé ibẹru jade o si le gbogbo ifarahan ìnilára! Nitori ibẹru máa ń mú ìjayà dání, ati wipe ẹni ti o sáábà ma nbẹru ko ti dagba rara ninu ife kò tíì dé ìpele dídàgbà nínù ìfẹ́ aláìlẹ́gàn.

Ní kété tí Ọlọ́run fi òye yé mi pé ìfẹ̀ Rẹ̀ máa ńlé ìbẹ̀rù jáde, mo wá mú ohun tí mo kọ yi wa si ojúṣe. A ni iṣoro pelu ohun ìrìnsẹ̀. Alérò pé ètò orí amóhùn máwòrán wá ti ńfẹ́ wá sí ìdádúró, a kò sì ní owó àti tẹ̀síwájú nínú ètò yí. A tẹ̀síwájú láti máa wá ọkọ̀ yí, ní ìrètí pé kò ní túká.

Ọlọ́run wá mú mi lọ́kàn le ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yí, Joyce, lo ọjọ́ òní láti fi ìfẹ́ hàn sími, kí o sì gbà mí láàyè lati fi ifẹ mi han si ọ. O ko nilo lati ṣe ohunkóhun. Okò nilo lati jẹ́ obìnrin onígbàgbọ́ ńlá. Ohun to nílò ni wipe ki o dúró ninu ìfẹ́ mi.

Báyìí, mo wá ńkọ orin, sí Ọlọrun, mo si ńgbádùn ara mí. Lójijì, mo gbọ́ ohùn ọkọ mi níbití a ńgbé ọkọ̀ pamọ́ sí lẹ́yìn ìsẹ́jú márùndínláàdọ́ta tó yẹ kí ó ti lọ sí ibi iṣẹ́ rẹ̀, ó ṣí ilẹ̀kùn ósì wípé “nkò lè wa ọkọ̀ wa kúrò ninu ọ̀pá jíà àkọ́kọ́. A nílò lati lọ tún ọkọ̀ náà ṣe.”

Mo pa ilẹ̀kùn dé mo sì ń rẹ́rìnín. Kìí ṣe ohun tó yẹ kí nṣe nìyí, bẹ́ẹ̀ ni ki se wipe mo ti pinnu lati ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni àkọ́kọ́, ó kàn wá bẹ́ẹ̀ ni. Nitori mo ti gba ki Ọlọrun fẹran mi, o jẹ́ kí ó ṣeéṣe fúnmi lati rẹ́rìnín ninu ìṣòro tó le yìí. Dídúró ninu ìfẹ́ Ọlọ́run máa ńṣílẹ̀kùn fún ìgbàgbọ́ wa lati bú jáde ninu wa dípò ibẹru. Mo wa bẹ̀rẹ̀ síní rẹ́rìnín, ìgbàgbọ́ nìyẹn. Mo mọ̀ wipe Ọlọrun fẹ́ wa, yíó ìi pèsè fún àìní wa.

Ábúráhàmù rẹ́rìnín ìgbàgbọ́, nígbàtí Ọlọrun sọ fun pe yio bi ọmọkùnrin kan, Aburahamu rẹrinin! O mọ̀ wipe kò

sí ọ̀nà àbáyọ, gẹgẹbi eniyan pe oun ati Sáráì le ní ọmọ láyé, ṣùgbọ́n ó gba Ọlọrun gbọ́, aye rẹ̀ sì já sí ẹ̀rín.

Mo gbàgbọ́ pe bi a ba wà ninu ipele yi o máa sílẹ̀kùn fún Ọlọ́run lati ràn wá lọ́wọ́ ní ọ̀nà tí yíò yàwá lẹ́nu. Tani yio ronú lati rẹ́rìnín nígbà tí ó bá wà nínú ìṣòro? Bíbeílì wipe Ọlọrun jókòọ́ ní ọ̀run o fi awọn ọ̀tá rẹ̀ rẹ́rìnín (wo Orin Dafidi 2:2-4). Bí Ọlọrun bá lè ṣe báyìí, àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Ó yá bẹ̀rẹ̀ síní rẹ́rìnín, rẹ́rìnín ìgbàgbọ́. Pàápàá jùlọ, Ọlọ́run fẹran rẹ. Tí Ọlọ́run bá ńṣe tìre ta ló lè kọjú ìjà sí ọ?

6

ÌFẸ́ AMÁA KÓNIMÓNRA

“Òfin yìị́ ni àwa sì rí gbà láti ọwọ́ Rẹ̀ wá, pé ẹni tí ó bá fẹ́ràn Ọlọ́run yíò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú.”

– 1 JOHANU 4:21

Ọmọ Ọlọ́run tó ṣọ̀wọ́n ni ọ́. Ó sọ fún wa nínú Deuteronọ́mì 7:6. Bí o bá mọ̀ wípé o ṣọ̀wọ́n fún Ọlọrun tí o sì ńgbé igbésí aye rẹ pẹlu ayọ̀ ati ìgboyà tí ó ye, èyí yíò ran gbogbo agbègbè rẹ lọ́wọ́ ní ọ̀nà tó dára. ìwo yíò lọ sínú ilé ìtajà pẹ̀lú ẹ̀rín lẹ́rẹ̀kẹ́ re, pẹ̀lú ìrònú pé a fẹ́ràn mi. Ayé mi ti dára. Èmi yio si jẹ́ alábùkún fún elòmíràn pẹ̀lí ìfẹ́ tí mo rí gbà lọ́wọ́ Ọlọrun. Inú rẹ yio máa dùn ní gbogbo ibi tí o bá lọ ìdùnnú re yìí yíọ̀ sì ran ẹlòmíràn. Orin Dáfídì 100:2 wípé kí á fi ayọ̀ sin Ọlọ́run!

Ní kété tí a bá mọ bí a ṣe wúwo lọ́wọ́ Ọlọ́run tó àti bí a ṣe jẹ́ ènìyàn ọ̀tọ̀, ìpinnu ìfẹ́ Rẹ̀ pẹ̀lú ìhùwàsí á dá lórí ìfihàn yí, a ó lè sàfihàn ìfẹ́ Rẹ̀ ní ọ̀nà tí aó fi mú àwọn ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ Ọlọ́run tó ńṣàn nínú rẹ yíò jẹ́ kí o kíyèsí àìní àwọn ẹlòmíràn àti wípé wàá lè fi ojú àánú wò wọ́n. ìfé Rè nínú rẹ yíò tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ìfòyà, o kò sì ní ní ìbẹ̀rù láti nọwọ́ ìfẹ́,sí elòmíràn. Ẹ̀rù ìkọ̀sílẹ̀, tàbí ìrẹ́nijẹ kò níbà ọ́, ìfẹ́ Ọlọ́run nínú rẹ yíò mú ọ

rí àìní ẹlòmíràn ati láti bá àìní wọ̀nyí pàdé.

Ọlọ́run fẹ́ kí o gbàgbọ́ nígbà tí o wípé, Òun yíò ṣe ohun ńlá láti ọwọ́ rẹ nítorí Jesu ńgbé inú rẹ. Gbẹ́kẹ̀ rẹ le kí o si gbàgbọ́ wípé Ó fẹ́ lò ọ́ láti fẹran awon eniyan ati lati ràn wọ́n lọ́wọ́. Rántí wípé ìfẹ́ pípé Ọlọ́run máa ńlé ẹ̀rù jáde, májẹ̀kí ìbẹ̀rù dè ọ́ mọ́lẹ̀ láti gbé ìgbésè ìgbàgbó.

Nkò lè bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ iye ìgbà tí mo ti dúró létí “bèbè odò ìgbàgbó” “létí bèbè ati ṣe ǹkan tó bá eniyan lẹ́rù, tó sì dàbí ẹni wipe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ bayi,” Máa bọ̀ Joyce, Máa bọ̀. Èmi yíò ti ọwọ́ rẹ ṣe ohun ńlá. Máa bọ̀.” Gbogbo ìgbà tí mo bá gbé ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ yìí tí mobọ́ sínú agbedeméjì ohun ti mo dáwọ́lé yìí, Ọlọ́run kò já mi kulẹ̀ rí.

Ǹjẹ́ o ti lẹ̀ mọ̀ ìdí tí mi ò kí ńfi ńdààmú ara mi nípa ìgbésẹ̀ tí mo fẹ́ gbé tàbí bẹ̀rù ìjákulẹ̀? Nítorí mo mọ̀ wípé Ọlọ́run fẹ́ràn mi. Ó fẹ́ mi, Ó sì mọ̀ wípé èmi náà fẹ́ràn òun pẹ̀lú, nípa Ore-Òfẹ́ Rẹ̀ mo ti fi ẹ̀mí mi lélẹ̀ fúnun. Tí o bá ṣe eléyìí, pé o fẹ́ràn Ọlọ́run Òun náà sì fẹ́ràn rẹ, kò sí ìsòro tí kì yíò lè borí rẹ nínú Kírístì.

Tóbá jẹ́ pe lóòọ́tọ́ lo ti pinnu láti ran ẹlòmíràn lọ́wọ́, Ọlọ́run yíò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. O kò nílò ipá tabi ìlàkàkà, o ní láti jọ̀wọ́ ara rẹ fún Ọlọ́run, Òun á sì ṣe gbogbo èyí tó kù. O le lérò wípé ẹ̀bùn rẹ kéré sùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà bí ohun kan bá ṣe kéré sí, ni agbára rẹ̀ ṣe máa ńpọ̀ tó.

Má ṣe lo ìgbésí ayé rẹ nínú ìmọtara –ẹni-nìkan nínú èyí tí wàá lo gbogbo agbára tí ó ní fún wíwá ohun gbogbo tí o

nílò fún ara rẹ nìkan - ṣoṣo. Sọ fún Ọlọ́run ohun tí o fẹ́ àti èyí tí o nílò kí o sì wá gbójú rẹ sókè sí Olúwa kí o lè sàkíyèsí ọ̀nà tí Ẹ̀mí Mímọ́ fẹ́ kí o gbà láti jẹ́ alábùkún fún àwon ènìyàn rẹ.

Ohun tí o bá ṣe fún ẹlòmíràn, Ọlọ́run yíò sanán padà fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Tí o bá ṣe aláìní, “jẹ́ ẹni tí ó ńkíyèsí irúgbìn”, kìí ṣe ẹni tí ó ńlépa “àìní nìkan.” Ìtumọ̀ èyí ni pé o níláti ṣe àfihàn ìfẹ́ sí ẹlòmíràn, Ọlọ́run tẹ́wọ́gba èyí gẹ́gẹ́bíi irúgbìn tí a gbìn fún ìkórè ohun tí a nílò nínú ayé wa.

Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ di ẹni ìbùkún, ṣùgbọ́n a ní láti ní òye ohun ti ibukun jẹ́. Mo fẹ́ ṣe àfiwé ibukun gẹgẹbi ọ̀nà Ọlọ́run láti bá àìní àwọn eniyan tó wá sí iwájú wa pàdé. Ìfẹ́ Ọlọ́run yíò fún ọ ní ipa láti fi aini àwọn ẹlomiran siwaju ti ara rẹ. Ǹjẹ́ o mọ̀ wípé Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ débi pé ó lè mú ọ ṣe àfihàn ìfẹ́ sí ẹlomiran, pàápàá àwọn tí kò ní ìfẹ́, àwọn oníwà búburú, àwon aláìmoore? A kò nílò ìkóra-eni ní ìjánu púpọ̀ láti fẹ́ràn awọn to fẹran wa, Sugbọn, a gbọ́dọ̀ ní ore-ọ̀fẹ́ lati fẹran awọn ti ko ni ifẹ wa pẹlu. Ifẹ Ọlọrun ti o ńsàn bí odò nínú wa lè ṣe èyí nítorí ìfẹ́ Rẹ̀ kìí ṣe lórí ipò tàbí àgbékàlé. Lọ́fẹ̀ẹ́ ni a gbàá, lọ́fẹ̀ẹ́ náà ni a ó fi fún ẹlomiran. Ifẹ kìí jáni kulẹ̀ kìí sìí sọ ìrètí nù lórí ẹnikẹ́ni. Ó lè gbà ọ́ tó ọdún kan. Ó lè gbà ọ́ tó ọdún márùn. O le to ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, sùgbọ́n ó tóbẹ́ẹ̀ ó sì jùbẹ́è lọ. Tí o bá ní ìnira nípa sùụ́rù àti ìfẹ́ tío fihàn sí ẹnití o ṣọ̀rọ̀ láti ní ìfẹ́ rẹ̀, ránti gbogbo ìgbàtí Ọlọ́run mú sùúrù fún ọ lati ni ifẹ rẹ nígbàtí Ó ńdúró dè ọ̀ pé kí Oun le yi o padà.

1 Kọ́ríntì 13 wipe ifẹ a máa músùụ́rù, a sì máa ṣerere pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, kìí wá ohun ti ara rẹ̀ nìkan, a kìí múu bínú, kìí hùwà àìtọ́. Àwọn àmúyẹ yìí ni Jesu dà léwa lórí nípa ìfẹ́ tí ó ní sí wa,

a lè mú wa sínú òbírípo kí á sì se fún àwọn tí a sá lọ́gbẹ́, àwon aṣáko tóún pòùngbẹ ìfẹ́ Ọlọ́run nínú ayé wọn.

Ọlọrun fẹran rẹ, o si fẹran gbogbo eniyan to wà ní àyíká rẹ. Ó fẹran wọn, bóyá ẹni tí ó ní ìgbàlà tàbí èyí tí kò ní, ó fẹ́ lò ọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun èlò láti fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn.

Má bẹ̀rù àti jáde síta. Ìfẹ́ Ọlọrun ńsọ ọ́ di òmìnira kúrò nínú ibẹru ati ìdálẹ́bi, ó sì ti fún ọ ní agbára lati fi ifẹ han ẹlomiran. Pinnu lati ṣe àjọpín ìfẹ́ Ọlọrun pèlú ẹlomiran. Ole bẹ̀rẹ̀ pẹlu ibanidorẹ pẹ̀lú eniyan. Múu wá sí ojúṣe lójojúmọ́ láti jẹ́ ẹnití ó nífẹ̀ẹ́ kí o sì jẹ́ orísun Ìbùkún sí àwọn eniyan nibi gbogbo ti o bá ńlọ.

Ìgbani lálejò fún ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ jẹ́ ọ̀nà kan láti fi ifẹ hàn, pàápàá jùlo sí ẹnití ó ńdágbé tí ọkàn rẹ̀ sì pòrúúru. Pe àwon eniyan si àsè àpèjẹ alé, Jẹ́kí awọn eniyan wá kí ọ nílé rẹ. Gba ọwọ́ lọ́wọ́ awọn eniyan ki osi rẹ́rìnín músẹ́. Dìmọ́ eniyan tabi sọ ọ̀rọ̀ tó ńgbéniró fún wọn. Fi ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ sí ojú iṣẹ́, bóyá kí o fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ gbé ẹnití ọkọ̀ tirẹ̀ bàjẹ́ lọ sí ibi iṣẹ́ rẹ̀. Yọjú sí àwọn ẹnití a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà sínú ilé iṣẹ́ níbi iṣẹ́ wọn bóyá o le ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ ojú – ilẹ̀ nínú ìlú tíwọn dé sí. Ọlọrun ní ohun pàtàkì kan tó fẹ́ kí o ṣe, ólè jẹ́ ǹkan kékeré èyi tí kò tóbi tí kò sì ṣe pataki sí ọ, ṣugbon o jẹ́ ohun to se pataki si Ọlọ́run. Gbogbo eniyan se pataki sí Ọlọrun.

Àwon eniyan kan wà tó jẹ́ wipe ìwọ nìkan ṣoṣo ni o lè dé ọ̀dọ̀ wọn. Bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run kíó fi ọ̀nà tí o gbà fi ìfẹ́ hàn sí wọn yé ọ, yí o sì kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ bí oó ṣe rìn.

7

ÌFẸ́ ỌLỌ́RUN ÁYÍ Ọ PADÀ

“Nínú èyi nì ìfẹ́ wà, kìí se pé àwa fẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n Òun fẹ́ wa, Ó sì rán ọmọ Rẹ̀ láti jẹ́ ètùtù fún ẹ̀sẹ̀ wa.”

– 1 JOHANU 4:10

Ọlọ́run fẹ́ràn wa, ṣụ̀gbọ́n mi ò lérò wípé àwọn ènìyàn lè ṣe àkàwé bí ìfẹ́ ńlá yìí ṣe tó àti bí Òun tìkalára Rẹ̀ ṣe fẹ́ wa tó. Ọlọ́run ti fihàn mí nínú àròjinlẹ̀ mi lórí àkọlé yìí, pé bí a bá mọ ìjìnlẹ̀ ifẹ nla aláìláfiwé èyí tí Ọlọ́run fẹ́ wa, aó gbé ìgbésẹ̀ ní ọ̀nà ti o yàtọ̀ sí, bí a ṣe ńṣe ní gbogbo ìgbà.

Ronú jinlẹ̀ lórí ìfẹ́ Ọlọ́run fún ayé rẹ. Ohun tí yíò yí ayé rẹ padà nìyí. Tí o bá kó ìríra ohun kan nípàtó nípa ara rẹ, níní ìgbàgbọ́ ati ìdánilójú wípé Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ nígbàtí ò ńdúró de àsepé Rẹ̀ lórí ibití àbùkù ayé rẹ wà, yíò mú ọ gbádùn ìrìn àjò ìyípadà rẹ.

Bí o ní ìpòrúru nípa àṣìṣe rẹ o kò níle yípadà, Rántí wípé Ọlọ́run máa ńṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ìgbàgbọ́ tòótọ́ máa ńmú wa wọ inú ìsinmi. Ní Hébérù 4. Ódà bíi ẹni wípé, púpọ̀

nínúawọn eniyan kòní àjọṣepọ̀ tó dánmọ́rán pẹ̀lú ara wọn. Won kò fẹran ara wọn àti pé ó ṣeéṣe kí wọn kó ìríra ara wọn pẹ̀lú. Tí o bá ńbá ara rẹ jìjàkadì lórí bó ṣe ńṣe ọ́, mo fẹ́ rán ọ létí pé o lè kó ìríra awọn ìwà búburú ti o ńhù, ṣùgbọ́n o kò gbọdọ̀ kó ìríra ara rẹ. Jesu kú fún ọ nítorí ìfẹ́ ńlá tí Ó ní síọ, Ó fẹ́ kí o gba ẹ̀bùn iyebíye Rẹ̀.

Bíbélì wipe, Nitori pe bi o ti ńrò ní ọkàn rẹ bẹ́èni o rí. (Owe 23:7). Tí inú rẹ kò bádùn sí ara rẹ ní gbogbo ìgbà, kíkọ ara-ẹni-sílẹ̀ láì náání pé o ṣe iyebíye, o kì yíò ní àlàáfíà àti ayọ̀ Ọlọ́run, yíò sì farahàn nínú ìhùwàsí rẹ. Àti pé nítorí, o kò tíì gba òtítọ́ agbára Ọlọ́run tí óún yíni padà mú pé, Ọlọ́run fẹ́ kí o máa lo àkókò rẹ pẹ̀lú Òun lójojúmọ́. Ohun to máa yíọ padà nìyí. Tí o kò bá ní àkókò pẹ̀lú Ọlọ́run, òún fi sí ipò tí kò ní lè ráyè ṣe ohun tó fẹ́ fún ọ. Àkọ́kò tí òún lò pẹ̀lú Ọlọ́run ní ìkọ̀kọ̀, ní fífẹ́ràn Ọlọ́run tí o sì ńfi ààyè gbàá láti fẹ́ ọ pẹ̀lú, èyí ni yíò mú ọ ní agbára, ìgboyà àti ìdàgbà sókè nínú Olúwa.

Púpọ̀ eniyan máa ńṣe àwáwí wọn kò sì fi àkókò wọn sínúu dídàgbà nínú ìbásepò pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó wù wọ́n kí won ní ìbásepọ̀ tó dára pẹ̀lú Rẹ̀. Ṣụ̀gbọ́n won kò lè kó ara won ní ìjánu láti dàgbà nínú ìwà rere nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ ninu ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ati àdúrà gbígbà. Bí o bá ní ìṣòro pẹ̀lú èyí, gbàdúrà kí o sì bèèrè kí Ọlọ́run ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé lílo àkókò ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run lójojúmọ́. Ohun tí ó dára jùlo nìyí tí ènìyàn lè ṣe.

Ìfẹ́ Ọlọ́run á yíọ lọ́kàn padà. Bí o bá ṣe ńní ìrírí ìfẹ́ Rẹ̀ tí o sì ńsàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, o wá ríi pé èrò ọkàn

rẹ ńyípadà. Wàá fẹ́ láti dàbí Jesu ẹnití ó fẹran rẹ. Mímọ̀ àti dídàgbà nínú ìwà bíi Ọlọ́run nínú ayé wa gbọ́dọ̀ jẹ́ ìlépa tí ó ga jù. Paulu wipe ìpinnu òun ni láti mọ Kristi àti agbára àjíǹde Rẹ̀ (wo Filipi 3:10).

Kíyèsi wípé kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́ tí Paulu wí yìí jẹ́ ohun ipinnu. Mo fẹ́ gbà ọ́ níyànjú láti ka ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run kún. O lè súnmọ́ Ọlọ́run típẹ́típẹ́ bío bá ṣe fẹ́; ó dá lórí iye àkọ́kò tí o pinnu láti lò pẹ̀lú Rẹ̀.

Bibeli wipe asojú Ọlọ́run ni wá àti wípé Òun ńgba ọ̀rọ̀ gbogbo aráyé rò nípasẹ̀ wa. (wo 2 Korinti 5:20). Ẹ̀kọ̀ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí gba ọkàn mi, ó sì mú mi ní èrò tuntun ní bí ó ṣese pàtàkì tó láti tẹ̀lé ìdarí Ẹ̀mí Mímọ́ bí ó ti ńṣisẹ́ nínú wa, bío ṣe ńyí wa padà tí ó sì ń tún wa ṣe fún èròǹgbà Ọlọ́run. Ìfẹ́ Ọlọ́run ni a tàn síwa lọ́kàn nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ (wo Romu 5:5). Gbàá, kí o sì gbádùn rẹ̀, kío sì jẹ́ kó yí ayé rẹ padà sí rere.

NÍNÍ ÌRÍRÍ ÌGBÉ AYÉ Ọ̀TUN

Bí o kò bá gba Jesu gẹ́gẹ́ bí Olúwa àti Olùgbàlà Rẹ, mò ńpè ọ́ pé kí o ṣe bẹ́ẹ̀ kánkán. Gba àdúrà yí pẹ̀lú ọkàn òtítọ́ kí o sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìrírí ìgbésí ayé tuntun ninu Kristi èyítí Ọlọ́run fi fún ọ.

Bàbá Olúwa, mo gbàgbọ́ ninu Jesu Kristi ọmọ Rẹ, Olùgbàlà aráyé. Mo gbàgbọ́ wipe ó kú lórí igi àgbélèbú fún mi ó sì ru gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ. Ó jíǹde kúrò ninu ikú nípasẹ̀ eléyìí, Ó jọba lórí ikịú àti isà òkú. Mo gbàgbọ́ wipe Jesu wà láàyè lọ́wọ́ lọ́wọ́. Ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Olódùmarè. Mo nílò Rẹ Jesu. Dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jìmí, gbà mí là, wọ inú ayé mi, mo fẹ́ di àtúnbí. Mo fẹ́ wà láàyè fún ọ. O ṣeun tóo gbàmílà tí O sì tún ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé tuntun fún ọ.

Nísisiyìí gbàgbọ́ wipe Jesu wà ní oókan àyà rẹ. Gbàgbọ́ pé a ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, o di olódodo nipa ẹ̀jẹ̀ Jesu, àti wipe wàá lọ sí ọ̀run rere ní ojó kan.

Mo rọ̀ ọ́ wipe kí o lọ sí ilé ìjọsìn tó dára, níbi tí wọ́n ti ńkó ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí o baà lè dàgbà nínú ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú Kristi. Ènìyàn máa ńyípadà nípa agbára ìfẹ́ Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ńṣiṣẹ́ ninu aye wa. Ó ṣe pàtàkì láti mọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jòhánà 8:31-32 wipe. Bí ẹ̀yin bá dúró ninu ọ̀rọ̀ mi nígbà náà ni ẹ̀yin jẹ́ ọmọ - ẹ̀yìn mi ní tòótọ́. Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yíò sì sọ yín di òmìnira.

Mo gbà ọ́ ní ìyànjú láti gbá ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí o sì gbìnín sí inú ọkàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí (2 Korinti 3:18) Bí o ti ńwọ inú ìwẹ́ mímọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ó pa ọ́ láradà sí àwòrán Jesu Kristi.

Jọ̀wọ́ kọ ìwé sími, sì jẹ́kí nmọ̀ bí o bá ti gba Jesu Kristi ní Olúwa ati Olùgbàlà rẹ. Kí o sì bẹ́èrè fún ìwé ọ̀fẹ́ lórí bí ó ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé tuntun nínú Kristi.

Pẹ̀lú Ìfẹ́,

Joyce

ÀDÚRÀ ÌGBÀLÀ

Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ, ó sì fẹ́ ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lúù rẹ, tí o kò bá tíì gba Jésù kiristì gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà rẹ, o lè ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsinyìí. Sáà sípayá Ọkàn rẹ síi kí o sì gba àdúrà yí.

“Baba, mo mọ̀ pé mo ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ, jọ̀wọ́ dárí jìn mí, wẹ̀ mí mọ́, mo ṣe ìlérí pé èmi yíò gba Jésù ọmọ rẹ gbọ́. Mo gbàgbọ́ pé Ó kú fún mi, ó kó ẹ̀ṣẹ̀ mi sí orí ara rẹ̀ nígbà tí ó kú lórí igi àgbelèbú. Mo gbàgbọ́ pé a jíi dìde kúrò nípò òkú. Mo jọ̀wọ́ ayé mi fún Jésù nísinsinyìí. Ẹṣé Baba fún ẹ̀bùn ìdáríjì àti ìyè áyérayé, ẹjọ̀wọ́ ẹ ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ayé mi fúnun yín, ní orúkọ Jésù. Àmín”

Bí o ti gba àdúrà yí láti ọkàn, Ọlórun ti gbà ọ́, ó ti fọ̀ọ́ mọ́, ó ti sọọ́ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìgbèkùn ikú ti ẹ̀mí. Wá àkókò láti ka àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí kí o sì jẹ́ kí Ọlọ́run bá ọ sọ̀rọ̀ nípa ìrìn àjò tuntun yìí pẹ̀lúu Rẹ̀.

Jòhánù 3:16 1Kọ́ríntì 15:3-4

Éfésù1:4 Éfésù 2:8-9

1Jòhánù 1:9 1Jòhánù 4:14-15

1Jòhánù 5:1 1Jòhánù 5:12-13

Gba àdúrà, kí o sì bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún Ilé Ìjọsìn tí ó gba Bíbélì gbọ́, tí ó sì leè ru ọ́ sókè láti dàgbà nínú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lúu Kírístì. Ọlọ́run wà pẹ̀lúù rẹ ní gbogbo ìgbà. Òun yíò sì tọ́ọ sọ́nà ní ọjọ́ dé ọjọ́, yíò sì fi ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun tí Òun fẹ́ fún ọ hàn sí ọ.

NÍPA ẸNI TÍ Ó KỌ ÌWÉ YÌÍ

JOYCE MEYER jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ògbóǹtarìgì Olùkọ́ni ní ẹ̀kọ́ Bibeli ní gbogbo àgbáyé, òǹkọ̀wé tí ìwé rẹ̀ tà jùlọ ní ìlú New York. Ìwé rẹ̀ ti ran ẹgbẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ àìmọye eniyan lọwọ lati ni ìrètí ìmúpadàbọ̀ sípò nípasẹ̀ Jesu Kristi. Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ Joyce Meyer, ó ti kọ onírúurú àkọlé pàápàá jùlo lórí ọkàn, ẹnu, ìwà àti ìṣe. Ọ̀nà àrà tí ó fi ńgbà bá àwon eniyan sọ̀rọ̀ lati ṣe àlàyé ní gbangba ohun tí Òun fúnra rẹ̀ ti làkọjá mú kí àwọn eniyan lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ìrírí tìre láyé kí won sì ṣe àmúlò rẹ̀. Joyce tikọ ìwé tó Ọgọ́rùnún, èyítí a ṣe ìtumọ̀ rẹ̀ sí oní rúurú èdè ọgọ́rùnún. Ó máa ńṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tó ìgbà méjìiá lọ́dún, tí ó sì ńkọ́ni bí a ṣe lè gbé ìgbé ayé ìdùnnú ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Láti bíi ọgbọ̀n odún sẹ́yìn, ìpàgọ̀ àwon obìnrin ti mú ogunlọ́gọ̀ àwọn obìnrin àìmọye ní gbogbo àgbáyé péjọ pọ̀ lójú kannáà lódọdún. Ohun tó ńmú inú Joyce dùn ni wipe kí ó máa se ìtọ́jú àwon tí a sá lọ́gbẹ́, èyí sì jẹ́ ìpìlẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ‘Hand of Hope’ ní gbogbo àgbáyé, pàápàá jùlọ ìlú tirẹ̀ gangan tí à ńpè ni St Louis ní Ìlẹ̀ Amẹ́ríkà.